Deuteronomy 30:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín lọpọlọpọ, ati àwọn ọmọ yín; àwọn ọmọ mààlúù yín, ati àwọn ohun ọ̀gbìn yín, nítorí inú OLUWA yóo tún dùn láti bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe inú dídùn sí àwọn baba yín,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA Ọlọrun rẹ yio si sọ ọ di pupọ̀ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, fun rere: nitoriti OLUWA yio pada wa yọ̀ sori rẹ fun rere, bi o ti yọ̀ sori awọn baba rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú ù rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èṣo ilẹ̀ rẹ. OLÚWA yóò tún mú inú dídùn sínú ù rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ.