Deuteronomy 31:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pe àwọn eniyan náà jọ, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àgbà, ati onílé ati àlejò, tí ó wà ninu ìlú yín, kí wọ́n lè gbọ́, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí wọ́n sì máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ninu òfin yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kó awọn enia na jọ, awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọde, ati alejò rẹ ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki nwọn ki o le gbọ́, ati ki nwọn ki o le kọ ati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ati ki nwọn ki o ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pe àwọn ènìyàn jọ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn àlejò tí ń gbé àwọn ìlú u yín kí wọn lè fetí sí i kí wọn sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ kí wọn sì rọra tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí.