Deuteronomy 31:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ ọ́n lè gbọ́ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ sí òkè odò Jọdani láti gbà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ki awọn ọmọ wọn, ti kò mọ̀, ki o le gbọ́, ki nwọn si kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngóke Jordani lọ lati gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ wọn tí wọn kò mọ òfin yìí, gbọdọ̀ gbọ́ kí wọn sì kọ́ láti bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ níwọ̀n ìgbà tí o tí ń gbé ní ilẹ̀ tí ò ń kọjá la Jọ́dánì lọ láti ni.”