Deuteronomy 31:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, ọjọ́ rẹ sunmọ-etile ti iwọ o kú: pè Joṣua, ki ẹ si fara nyin hàn ninu agọ́ ajọ, ki emi ki o le fi aṣẹ lé e lọwọ. Mose ati Joṣua si lọ, nwọn si fara wọn hàn ninu agọ́ ajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Móṣè pé, “Ọjọ́ ikú rẹ ti súnmọ́tílé báyìí. Pe Jóṣúà kí ẹ sì fi ara yín hàn nínú àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti fi àṣẹ fún un.” Nígbà náà ni Móṣè àti Jóṣúà wá, wọ́n sì fara wọn hàn níbi àgọ́ àjọ.
Recommended Reading