Deuteronomy 31:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Inú mi yóo ru sí wọn ní ọjọ́ náà, èmi náà óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀, n óo mú ojú mi kúrò lára wọn, n óo sì pa wọ́n run. Oríṣìíríṣìí ibi ati wahala ni yóo bá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo máa wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ǹjẹ́ nítorí pé kò sí Ọlọrun wa láàrin wa kọ́ ni gbogbo ibi wọnyi fi dé bá wa?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ́ na, emi o si kọ̀ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ̀ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹ̃ ti nwọn o si wi li ọjọ́ na pe, Kò ha jẹ́ pe nitoriti Ọlọrun wa kò sí lãrin wa ni ibi wọnyi ṣe bá wa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni èmi yóò bínú sí wọn èmi yóò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀; èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò fún wọn, wọn yóò sì parun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti ìṣòro yóò wá sórí wọn, àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ìpọ́njú wọ̀nyí kò wá sórí i wa nítorí Ọlọ́run wa kò sí pẹ̀lú u wa?’