Deuteronomy 31:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, kọ orin yìí sílẹ̀ nisinsinyii kí o sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kí orin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi lọ́dọ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, kọwe orin yi fun ara nyin, ki ẹ fi kọ́ awọn ọmọ Israeli: fi i si wọn li ẹnu, ki orin yi ki o le ma jẹ́ ẹrí fun mi si awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní báyìí kọ ọ́ kalẹ̀ fúnra à rẹ orin yìí kí o sì kọ ọ́ sí Ísírẹ́lì kí o sì jẹ́ kí wọn kọ ọ́ kí ó lè jẹ́ ẹ̀rí ì mi sí wọn.