Deuteronomy 31:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sìn wọn, nwọn a si kẹ́gan mi, nwọn a si dà majẹmu mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo ti mú wọn wá sí ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí ní ìbúra fún àwọn baba ńlá wọn, àti nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí ó sì tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì gbilẹ̀, wọn yóò yí padà sí ọlọ́run mìíràn wọn yóò sì sìn wọ́n, wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀, wọn yóò sì da májẹ̀mú mi.