Deuteronomy 31:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ẹ̀yà yín wá sọ́dọ̀ mi, ati gbogbo àwọn olórí ninu yín, kí àwọn náà lè máa gbọ́ bí mo ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ sì pe ọ̀run ati ayé láti ṣe ẹlẹ́rìí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pè gbogbo awọn àgba ẹ̀ya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọ̀rọ wọnyi li etí wọn ki emi ki o si pè ọrun ati aiye jẹri tì wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ péjọ pọ̀ ṣíwájú ù mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etíìgbọ́ ọ́ wọn.