Deuteronomy 31:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá pe Joṣua, ó sọ fún un níwájú gbogbo àwọn eniyan Israẹli, pé, “Múra gírí, kí o sì mú ọkàn gidigidi nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn eniyan wọnyi lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun ti búra fún àwọn baba wọn pé òun yóo fi fún wọn. Ìwọ ni o óo sì fi lé wọn lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si pè Joṣua, o si wi fun u li oju gbogbo Israeli pe, Ṣe giri ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio bá awọn enia yi lọ si ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba wọn, lati fi fun wọn; iwọ o si mu wọn gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè pe Jóṣúà ó sì wí fún un níwájú gbogbo Ísírẹ́lì pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí OLÚWA búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrin wọn bí ogún wọn.