Deuteronomy 31:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Móṣè kọ òfin yìí kalẹ̀ ó sì fi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, tí ń gbé àpótí i májẹ̀mú OLÚWA, àti fún gbogbo àwọn àgbà ní Ísírẹ́lì.