Deuteronomy 32:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn, n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí. Nítorí olóríkunkun ni wọ́n, àwọn alaiṣootọ ọmọ!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Emi o pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, emi o si ma wò bi igbẹhin wọn yio ti ri; nitori iran alagídi ni nwọn, awọn ọmọ ninu ẹniti kò sí igbagbọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn, èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí; nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí, àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.