Deuteronomy 32:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí oriṣa lásánlàsàn, wọn sọ èmi Ọlọrun di òjòwú; wọn sì ti fi àwọn ère wọn mú mi bínú. Nítorí náà, èmi náà óo lo àwọn eniyan lásánlàsàn láti mu àwọn náà jowú, n óo sì lo aṣiwèrè orílẹ̀-èdè lásánlàsàn kan láti mú wọn bínú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti fi ohun ti ki iṣe Ọlọrun mu mi jowú; nwọn si fi ohun asan wọn mu mi binu: emi o si fi awọn ti ki iṣe enia mu wọn jowú; emi o si fi aṣiwere orilẹ-ède mu wọn binu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run, wọ́n sì fi ohun aṣán an wọn mú mi bínú. Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn; èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀ èdè.