Deuteronomy 32:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó, bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀. Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́, gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idà li ode, ati ipàiya ninu iyẹwu, ni yio run ati ọmọkunrin ati wundia, ọmọ ẹnu-ọmu, ati ọkunrin arugbo elewu irun pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Idà ní òde, àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù. Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá, ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú.