Deuteronomy 32:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre, yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́, ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn, tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn, kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe OLUWA yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si kãnu awọn iranṣẹ rẹ̀; nigbati o ba ri pe agbara wọn lọ tán, ti kò si sí ẹnikan ti a sé mọ́, tabi ti o kù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.