Deuteronomy 32:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀, yóo sì mu àmuyó. Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi. N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí, ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́, ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn, gbogbo wọn ni n óo pa.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o mu ọfà mi rin fun ẹ̀jẹ, idà mi o si jẹ ẹran; ninu ẹ̀jẹ ẹni pipa ati ti igbekun, lati ori awọn aṣaju ọtá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀, nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran: Ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn, orí àwọn asáájú ọlá.”