Deuteronomy 32:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀. Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà, yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ ma yọ̀, ẹnyin orilẹ-ède, pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on o gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀, yio si gbẹsan lara awọn ọtá rẹ̀, yio si ṣètutu fun ilẹ rẹ̀, ati fun awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹyọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀; yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta a rẹ̀ yóò sì se ètùtù fún ilẹ̀ rẹ̀ àti ènìyàn.