Deuteronomy 32:51 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti ẹnyin ṣẹ̀ si mi lãrin awọn ọmọ Israeli ni ibi omi Meriba-Kadeṣi, li aginjù Sini; nitoriti ẹnyin kò yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibi omi Móríbà Kádésì ní ihà Ṣínì àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrin àwọn ọmọ Isírẹ́lì.