Deuteronomy 32:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé, gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí atóbijù fi ogún àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn, nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn, ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.