Deuteronomy 33:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé: “Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò, OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo, ó sì ń gbé ààrin wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati niti Benjamini o wipe, Olufẹ OLUWA yio ma gbé li alafia lọdọ rẹ̀; on a ma bò o li ọjọ́ gbogbo, on a si ma gbé lãrin ejika rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ti Bẹ́ńjámínì ó wí pé: “Jẹ́ kí olùfẹ́ OLÚWA máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́, ẹni tí OLÚWA fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrin èjìká rẹ̀.”