Deuteronomy 33:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù, Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára, tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu, ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Akọ́bi akọmalu rẹ̀, tirẹ̀ li ọlánla; iwo rẹ̀ iwo agbanrere ni: on ni yio fi tì awọn enia, gbogbo wọn, ani opin ilẹ: awọn si ni ẹgbẹgbãrun Efraimu, awọn si ni ẹgbẹgbẹrun Manasse.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọlá ńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù; ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni. Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀ èdè, pàápàá títí dé òpin ayé. Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúráímù, àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.”