Deuteronomy 33:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè, wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀. Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun, ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o pè awọn enia na sori òke; nibẹ̀ ni nwọn o ru ẹbọ ododo: nitoripe nwọn o ma mu ninu ọ̀pọlọpọ okun, ati ninu iṣura ti a pamọ́ ninu iyanrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo, wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkun, nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”