Deuteronomy 33:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wá láti orí òkè Sinai, ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu, ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani. Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́, ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé: “OLÚWA ti Sínáì wá, ó sì yọ sí wọn láti Ṣéírì wá ó sì tàn án jáde láti òkè Páránì wá. Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn ún àwọn mímọ́ wá láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan amúbíiná ti jáde fún wọn wá.