Deuteronomy 33:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ta ló tún dàbí yín, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà? OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín, òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun. Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alafia ni fun iwọ, Israeli: tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwọ́ OLUWA gbàla, asà iranlọwọ rẹ, ati ẹniti iṣe idà ọlanla rẹ! awọn ọtá rẹ yio si tẹriba fun ọ; iwọ o si ma tẹ̀ ibi giga wọn mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbùkún ni fún ọ, Ísírẹ́lì, ta ni ó dà bí ì rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ OLÚWA? Òun ni àṣà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọlá ńlá rẹ̀. Àwọn ọ̀ta rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”