Deuteronomy 33:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn kò ka òbí àwọn sí, ju ìwọ OLUWA lọ; wọ́n kọ àwọn arakunrin wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣá àwọn ọmọ wọn tì. Nítorí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, wọ́n sì ń pa majẹmu rẹ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé, ‘Èmi kò buyì fún wọn.’ Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.