Deuteronomy 34:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA wí fún un pé, “Ilẹ̀ tí mo búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé, n óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn nìyí, mo jẹ́ kí o rí i, ṣugbọn o kò ní dé ibẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun u pe, Eyi ni ilẹ ti mo bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Emi o fi i fun irú-ọmọ rẹ: emi mu ọ fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ ki yio rekọja lọ sibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ní OLÚWA sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò débẹ̀.”