Deuteronomy 4:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ fi ọkàn sí àwọn ìlànà ati òfin tí mò ń kọ yín yìí, kí ẹ máa tẹ̀lé wọn, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ń mu yín lọ, kí ẹ sì lè gbà á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NJẸ nisisiyi Israeli, fetisi ìlana ati idajọ, ti emi nkọ́ nyin, lati ṣe wọn; ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ si lọ igba ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin fi fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbọ́ Ísírẹ́lì, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín.