Deuteronomy 4:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, mo níláti kú ní ìhín yìí, n kò gbọdọ̀ rékọjá sí òdìkejì Jọdani, ṣugbọn ẹ̀yin óo rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, ẹ óo sì gba ilẹ̀ dáradára náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o kú ni ilẹ yi, emi ki yio gòke odò Jordani: ṣugbọn ẹnyin o gòke ẹnyin o si gbà ilẹ rere na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdì kejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà.