Deuteronomy 4:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹ bá ní ọmọ, ati àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà; bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀, nípa yíyá ère ní àwòrán ohunkohun, ati nípa ṣíṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ó lè mú un bínú,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba bi ọmọ, ati ọmọ ọmọ, ti ẹ ba si pẹ ni ilẹ na, ti ẹ si bà ara nyin jẹ́, ti ẹ si ṣe ere finfin, tabi aworán ohunkohun, ti ẹ si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA Ọlọrun rẹ lati mu u binu:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́: Bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yòówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú.