Deuteronomy 4:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ọ̀run ati ayé ń gbọ́ bí mo ti ń sọ yìí, pé ẹ óo parun patapata lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ gbà ní òdìkejì Jọdani. Ẹ kò ní pẹ́ níbẹ̀ rárá, ṣugbọn píparun ni ẹ óo parun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo pè ọrun ati aiye jẹri si nyin li oni, pe lọ́gan li ẹnyin o run kuro patapata ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a; ẹnyin ki yio lò ọjọ́ nyin pẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin o si run patapata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo pe ọ̀run àti ayé láti jẹ́rìí takò yín lónìí, pé kíákíá ni ẹ ó parun ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń la Jọ́dánì kọjá lọ láti gbà. Ẹ kò ní pẹ́ ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò run pátapáta.