Deuteronomy 4:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ lọ wádìí wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ rí kí wọ́n tó bí yín, láti ọjọ́ tí Ọlọrun ti dá eniyan, ẹ wádìí káàkiri jákèjádò gbogbo àgbáyé bóyá irú nǹkan ńlá báyìí ṣẹlẹ̀ rí, tabi wọ́n pa á nítàn rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bère nisisiyi niti ọjọ́ igbãni, ti o ti mbẹ ṣaju rẹ, lati ọjọ́ ti Ọlọrun ti dá enia sori ilẹ, ki o si bère lati ìha ọrun kini dé ìha keji, bi irú nkan bi ohun nla yi wà rí, tabi bi a gburó irú rẹ̀ rí?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ bèèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ bèèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkì báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí?