Deuteronomy 4:46 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nígbà tí wọ́n dé òdìkejì odò Jọdani, ní àfonífojì tí ó dojú kọ Betipeori, ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni. Mose ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Sihoni nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ìha ẹ̀bá Jordani, ni afonifoji ti o kọjusi Beti-peori, ni ilẹ Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni, ẹniti Mose ati awọn ọmọ Israeli kọlù, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Bétí Péórì ní ìlà oòrùn Jọ́dánì; ní ilẹ̀ Ṣíhónì, ọba àwọn Ámórì tí ó jọba Hésíbónì tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Éjíbítì bọ̀.