Deuteronomy 4:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Mo ti kọ yín ní ìlànà ati òfin gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún mi, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, emi ti kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, bi OLUWA Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹnyin ki o le ma ṣe bẹ̃ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kíyèsí i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí OLÚWA Ọlọ́run-ùn mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.