Deuteronomy 4:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn, wọn yóo sì sọ yín di ọlọ́gbọ́n ati olóye lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Orílẹ̀-èdè tí ó bá gbọ́ nípa àwọn ìlànà ati òfin wọnyi yóo wí pé, dájúdájú ọlọ́gbọ́n ati amòye eniyan ni yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ pa wọn mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; nitoripe eyi li ọgbọ́n nyin ati oye nyin li oju awọn orilẹ-ède, ti yio gbọ́ gbogbo ìlana wọnyi, ti yio si wipe, Ọlọgbọ́n ati amoye enia nitõtọ ni orilẹ-ède nla yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ máa kíyèsí wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀ èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀ èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.”