Deuteronomy 5:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà ati àwọn òfin tí n óo kà fun yín lónìí; ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
MOSE si pè gbogbo Israeli, o si wi fun wọn pe, Israeli, gbọ́ ìlana ati idajọ ti emi nsọ li etí nyin li oni, ki ẹnyin ki o le kọ́ wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ́, lati ma ṣe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì wí pé: Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etíìgbọ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.