Deuteronomy 5:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA Ọlọrun rẹ. Ní ọjọ́ náà, o kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati àwọn ọmọ rẹ obinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ, ati mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àlejò tí ń gbé ilẹ̀ rẹ; kí iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin rẹ lè sinmi bí ìwọ náà ti sinmi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọjọ́ keje li ọjọ́-isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ, ati ohunọ̀sin rẹ kan, ati alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ; ki ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ki o le simi gẹgẹ bi iwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọjọ́ kéje ni ọjọ́ ìsinmi sí OLÚWA Ọlọ́run yín. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà yálà ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí àwọn ọmọ rẹ obìnrin, tàbí àwọn ẹrú ọkùnrin tàbí ẹrú obìnrin yín tàbí màlúù yín, tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín, tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ẹran yín, tàbí àwọn àlejò yín, kí àwọn ẹrú-kùnrin àti ẹrú-bìnrin yín le è sinmi, bí i yín.