Deuteronomy 5:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ranti pé, ìwọ pàápàá ti jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti rí, ati pé OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó fi agbára rẹ̀ mú ọ jáde. Nítorí náà ni OLUWA Ọlọrun rẹ fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si ranti pe iwọ ti ṣe iranṣẹ ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ibẹ̀ jade wá nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa: nitorina li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe paṣẹ fun ọ lati pa ọjọ́-isimi mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ rántí pé ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì rí, àti pé OLÚWA Ọlọ́run yín yọ yín kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá, àti nína ọwọ́ rẹ̀. Torí èyí ni OLÚWA Ọlọ́run yín ṣe pàṣẹ fún un yín láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́.