Deuteronomy 5:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Àwọn òfin tí OLUWA fún gbogbo yín nìyí, nígbà tí ẹ fi péjọ lẹ́sẹ̀ òkè, tí ó fi fi ohùn rara ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná ati ìkùukùu, ati òkùnkùn biribiri. Àwọn òfin yìí nìkan ni ó fun yín, kò sí òmíràn lẹ́yìn wọn, ó kọ wọ́n sára tabili òkúta meji, ó sì kó wọn fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀rọ wọnyi ni OLUWA sọ fun gbogbo ijọ nyin lori òke lati ãrin iná, awọsanma, ati lati inu òkunkun biribiri wá, pẹlu ohùn nla: kò si fi kún u mọ́. O si kọ wọn sara walã okuta meji, o si fi wọn fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ OLÚWA tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrin iná, ìkùukù àti òkùnkùn biribiri: Kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú sílétì méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.