Deuteronomy 5:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitoripe emi OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara iran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ láti sìn wọ́n. Torí pé èmi OLÚWA Ọlọ́run yín Ọlọ́run owú ni mí, tí í fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹ́ta àti ẹ̀kẹ́rin ní ti àwọn tí ó kórìíra mi.