Deuteronomy 6:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó tọ́, ati ohun tí ó yẹ lójú OLUWA; kí ó lè dára fun yín, kí ẹ lè lọ gba ilẹ̀ dáradára tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o ma ṣe eyiti o tọ́, ti o si dara li oju OLUWA: ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wọ̀ ilẹ rere nì lọ ki o si gbà a, eyiti OLUWA bura fun awọn baba rẹ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú OLÚWA, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.