Deuteronomy 6:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘A ti jẹ́ ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ijipti rí, ṣugbọn agbára ni OLUWA fi kó wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun ọmọ rẹ pe, Ẹrú Farao li awa ti ṣe ni Egipti; OLUWA si fi ọwọ́ agbara mú wa jade lati Egipti wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún un pé: “Ẹrú Fáráò ní ilẹ̀ Éjíbítì ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n OLÚWA fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Éjíbítì.