Deuteronomy 6:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ máa tẹ̀lé àwọn òfin náà, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣe ìlérí fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina gbọ́, Israeli, ki o si ma kiyesi i lati ṣe e; ki o le dara fun ọ, ati ki ẹnyin ki o le ma pọ̀si i li ọ̀pọlọpọ, bi OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ ti ṣe ileri fun ọ, ni ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì ṣọ́ra láti gbọ́ran, kí ó bá à lè dára fún ọ, kí o bá à lè gbilẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba rẹ ti ṣèlérí fún ọ.