Deuteronomy 7:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá ko yín wọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ yìí, tí ẹ bá gba ilẹ̀ náà, tí OLUWA sì lé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè jáde fun yín, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hiti, Girigaṣi, Amori, Kenaani, Perisi, Hifi, Jebusi, àní àwọn orílẹ̀-èdè meje tí wọ́n tóbi jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí OLÚWA Ọlọ́run yín bá mú u yín dé ilẹ̀ náà, tí ẹ ó wọ̀ lọ láti gbà, tí ó sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè kúrò níwájú u yín: Àwọn ará Hítì, Gígásì, Ámórì, Kénánì, Pérésì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì: Àwọn orílẹ̀ èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ,