Deuteronomy 7:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Píparun ni ẹ óo pa gbogbo àwọn eniyan tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi lé yín lọ́wọ́ run, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ bọ àwọn oriṣa wọn, nítorí ohun ìkọsẹ̀ ni wọn yóo jẹ́ fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si run gbogbo awọn enia ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi fun ọ; oju rẹ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn awọn oriṣa wọn; nitoripe idẹkùn li eyinì yio jẹ́ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ènìyàn tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátapáta. Ẹ má ṣe sàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.