Deuteronomy 7:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ ranti àwọn àrùn burúkú tí ẹ fi ojú ara yín rí, àwọn àmì ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ agbára tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe kí ó tó kó yín jáde. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe sí gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idanwò nla ti oju rẹ ri, ati àmi, ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi mú ọ jade: bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio ṣe si gbogbo awọn enia na ẹ̀ru ẹniti iwọ mbà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ sáà fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. OLÚWA Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù.