Deuteronomy 7:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Díẹ̀díẹ̀ ni Ọlọrun yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí lọ. Kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ẹ óo pa gbogbo wọn run, kí àwọn ẹranko burúkú má baà pọ̀ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ju agbára yín lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA Ọlọrun rẹ yio tì awọn orilẹ-ède na jade diẹdiẹ niwaju rẹ: ki iwọ ki o máṣe run wọn tán lẹ̃kan, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba pọ̀ si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò ní gbà yín láàyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko ìgbẹ́ má baà gbilẹ̀ sí i láàrin yín.