Deuteronomy 7:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sísun ni kí ẹ sun gbogbo àwọn ère oriṣa wọn; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò wúrà tabi fadaka tí ó wà lára wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ kó wọn fún ara yín, kí wọn má baà di ohun ìkọsẹ̀ fun yín, nítorí ohun ìríra ni wọ́n lójú OLUWA Ọlọrun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ere finfin oriṣa wọn ni ki ẹnyin ki o fi iná jó: iwọ kò gbọdọ ṣe ojukokoro fadakà tabi wurà ti mbẹ lara wọn, bẹ̃ni ki o máṣe mú u fun ara rẹ, ki o má ba di idẹkùn fun ọ; nitoripe ohun irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹkùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí OLÚWA Ọlọ́run yín.