Deuteronomy 7:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò sì gbọdọ̀ mú ohun ìríra wọ ilé yín, kí ẹ má baà di ẹni ìfibú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ohun ìfibú. Ẹ níláti kórìíra wọn, kí ẹ sì yàgò fún wọn, nítorí ohun ìfibú ni wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ mú ohun irira wá sinu ile rẹ, ki iwọ ki o má ba di ẹni ifibú bi rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o korira rẹ̀ patapata, ki iwọ ki o si kà a si ohun irira patapata; nitoripe ohun ìyasọtọ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má bàá di ẹni ìparun bí i rẹ̀. Ẹ kóríra rẹ̀ kí ẹ sì kàá sí ìríra pátapáta, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni.