Deuteronomy 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, wọn óo yí àwọn ọmọ yín lọ́kàn pada, wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé èmi OLUWA mọ́. Àwọn oriṣa ni wọn óo máa bọ, èmi OLUWA yóo bínú si yín nígbà náà, n óo sì pa yín run kíákíá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nwọn o yi ọmọkunrin rẹ pada lati ma tọ̀ mi lẹhin, ki nwọn ki o le ma sìn ọlọrun miran: ibinu OLUWA o si rú si nyin, on a si run ọ lojiji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
torí pé wọ́n á yí àwọn ọmọ yín padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú OLÚWA yóò sì wá sórí yín, yóò sì run yín kíákíá.