Deuteronomy 7:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, ẹni mímọ́ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA Ọlọrun yín ti yàn yín, láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní gbogbo ayé, pé kí ẹ jẹ́ ohun ìní fún òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, OLÚWA Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrin gbogbo ènìyàn lórílẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.