Deuteronomy 8:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè máa bí sí i, kí ẹ sì lè lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
GBOGBO ofin ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati ṣe, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹnyin si ma pọ̀ si i, ki ẹnyin si wọnu rẹ̀ lọ lati gbà ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kíyèsí láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ báà le yè kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí OLÚWA fìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.